Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 21:15-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ọlọ́run sì rán ańgẹ́lì láti pa Jérúsálẹ́mù run. Ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì ti ń ṣe èyí, Olúwa sì ríi. Ó sì káàánú nítorí ibi báà, ó sì wí fún áńgẹ́lì tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Ańgẹ́lì Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.

16. Dáfídì sì wòkè ó sì rí áńgẹ́lì Olúwa dúró láàrin ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ Rẹ̀ tí ó sì nàá sórí Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà Dáfídì àti àwọn àgbààgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.

17. Dáfídì sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo paláṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò dára, wọ̀nyí ni àgùntàn. Kí ni wọ́n ṣe? Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdíle mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-àrùn yìí kí ó dúró lóri àwọn ènìyàn rẹ.”

18. Nígbà náà ańgẹ́lì Olúwa náà pàṣẹ̀ fún Gádì láti sọ fún Dáfídì láti lọ sókè kí ó sì kọ́ pẹpẹ fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínánì ará Jébúsì.

19. Bẹ́ẹ̀ni Dáfídì sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gádì ti sọ ní orúkọ Olúwa.

20. Nígbà tí Órínánì sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí áńgẹ́lì; àwọn ọmọ Rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú Rẹ̀ pa ará wọn mọ́.

21. Nígbà náà Dáfídì sì súnmọ́, Nígbà tí Órínánì sì wò tí ó sì rí, ó sì kúrò ní ilẹ̀ ìpakà ó sì doju bolẹ̀ níwájú Dáfídì pẹ̀lú ojú Rẹ̀ ní ilẹ̀.

22. Dáfídì sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè kọ́ pẹpẹ fún Olúwa, kí àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ènìyàn lè dúró. Tàá fún mi ní iye owó kíkún.”

23. Órínánì ni ó sọ fún Dáfídì pé, “Gbà á! Jẹ́ kí Olúwa ọba mi kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú Rẹ̀. Woó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ ọrẹ ṣiṣun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”

24. Ṣùgbọ́n ọba Dáfídì dá Órínánì lóhùn pé, “Rárá, mo wà lórí àti san iye owó rẹ ní pípé, èmi kò sì ní mú fún Olúwa èyí tí ó jẹ́ tìrẹ, tàbí láti rú ẹbọ ọrẹ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”

25. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Órínánì nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.

26. Dáfídì sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì ní ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọrẹ àlàáfíà. Ó sì pe orúkọ Olúwa, Olúwa sì da lóhùn pẹ̀lú iná láti òkè ọ̀run lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ ṣíṣun.

27. Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí ańgẹ́lì, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ Rẹ̀.

28. Ní àkókò náà nígbà tí Dáfídì sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínán ará Jébúsì, ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun níbẹ̀.

29. Àgọ́ Olúwa tí Mósè ti ṣe ní ihà, àti pẹpẹ ẹbọ ọrẹ ṣíṣun wà lórí ibi gíga ní Gíbíónì ní àkókò náà.

30. Ṣùgbọ́n Dáfídì kò lè lọ ṣíwájú Rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ ańgẹ́lì Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 21