Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 18:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Dáfídì mú apata wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadésérì gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jérúsálẹ́mù.

8. Láti Tébà àti Kúnì, ìlú tí ó jẹ́ ti Hádádéṣérì, Dáfídì mú ọ̀pọ̀ tánganran tí Ṣólómónì lò láti fi ṣe òkun tan-gan-ran, àwọn òpó àti orísìí ohun èlò tan-gan-ran.

9. Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti borí gbogbo ọmọ ogun Hádádéṣérì ọba Ṣóbà.

10. Ó rán ọmọ Rẹ̀ Ádórámì sí ọba Dáfídì láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun Rẹ̀ nínú ogun lórí Hádádéṣérì, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tóù. Ádórámì mú oríṣiríṣi ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti tan-gan-ran wá.

11. Ọba Dáfídì ya ohun èlò wọ̀n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí: Édómù àti Móábù, ará Ámónì àti àwọn ará Fílístínì àti Ámálékì.

12. Ábíṣáì ọmọ Ṣeruíà, lu méjìdínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Édómù bolẹ̀ ní àfonífojì iyọ̀.

13. Ó fi Gárísónì sí Édómù, gbogbo àwọn ará Édómù sì ń sìn ní abẹ́ Dáfídì. Olúwa fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

14. Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Jóábù ọmọ Ṣérúyà jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16. Ṣádókù ọmọ Áhítúbì àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣáfíṣà jẹ́ akọ̀wé;

17. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ́ olórí àwọn kérétì àti pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ àwọn olóyè onísẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 18