Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 18:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Jóábù ọmọ Ṣérúyà jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16. Ṣádókù ọmọ Áhítúbì àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣáfíṣà jẹ́ akọ̀wé;

17. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ́ olórí àwọn kérétì àti pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ àwọn olóyè onísẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 18