Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 17:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin Rẹ̀, ó sọ fún Nátanì wòlíì pé, Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpèpè (igi) ààfin kédárì nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wà lábẹ́ àgọ́

2. Nátanì dá Dáfídì lóhùn pé, Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.

3. Ní àsálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Nátanì wá, wí pé:

4. “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.

5. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.

6. Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 17