Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 15:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti kọ́ ilé fún ara Rẹ̀ ní ìlú Dáfídì. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un.

2. Nígbà náà Dáfídì wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Léfì ni ó lè gbé Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpóti ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Rẹ̀ títí láé.

3. Dáfídì kó gbogbo àwon ọmọ Ísírélì jọ ní Jérúsálẹ́mù láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún un.

4. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ọmọ Léfì tí Dáfídì pèjọ papọ̀:

5. Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kóhátì;Úríélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

6. Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Mórárì;Ásaíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

7. Àádóje nínú àwọn ọmọ Gésóní;Jóẹ́lì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

8. Igba nínú àwọn ọmọ Élísáfálì;Ṣémáíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

9. Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hébírónì;Élíélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

10. Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Húsíélì;Ámínádábù olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

11. Dáfídì sì ránṣẹ́ pe Ṣádókù, Ábíátarì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Úríélì, Ásáíà. Jóẹ́lì, Ṣémáíà, Élíélì àti Ámínádábù tí wọ́n jẹ́ Léfì.

12. Ó sì fí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Léfì; ẹ̀yin àti àwọn Léfì ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

13. Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Léfì kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa ya ìbínú Rẹ̀ lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.

14. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Ísírélì.

15. Nígbà náà ni àwọn Léfì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn. Gẹ́gẹ́ bí Mósè ti paá láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

16. Dáfídì sọ fún àwọn olórí àwọn Léfì láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orin pisalitérì, dùùrù, àti Ṣíḿbálì.

17. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Léfì yan Hámánì ọmọ Jóẹ́lì; àti nínú àwọn arákùnrin Rẹ̀, Ásáfù ọmọ Bérékíà, àti nínú àwọn ọmọ Mérárì arákùnrin wọn, Étanì ọmọ Kúṣáíà;

18. àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Ṣekaríyà, Jásíélì; Ṣémírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíféléhù, Míkíméíà, àti àwọn asọ́bodè Obedi-Edomu àti Jélíélì.

19. Àwọn akọrin sì ni Hémánì, Ásáfù, àti Étanì ti àwọn ti kíḿbálì idẹ tí ń dún kíkan;

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 15