Nígbà náà Dáfídì wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Léfì ni ó lè gbé Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpóti ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Rẹ̀ títí láé.