Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 11:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Lẹ́yìn Rẹ̀ sì ni Élíásárì ọmọ Dódáì àwọn ará Áhóhì, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára.

13. Ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pásídámímù nígbà tí àwọn ará Fílístínì kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà báálì. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Fílístínì.

14. Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárin pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Fílístínì mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.

15. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n (30) ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dáfídì wá lọ sí orí àpáta nínú ìhò Ádúlámù; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Fílístínì sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Réfáímù.

16. Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

17. Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu?

18. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa.

19. “Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí!” ó wí pé. “Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú.Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

20. Ábíṣáì arákùnrin Jóábù ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.

21. Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.

22. Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan

23. Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀.

24. Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin. Bénáìá ọmọ Jéhóíádà; ohun náà pẹ̀lú sì di ọlálá gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 11