1. OLUWA jọba; jẹ ki awọn enia ki o wariri: o joko lori awọn kerubu; ki aiye ki o ta gbọ̀ngbọ́n.
2. Oluwa tobi ni Sioni: o si ga jù gbogbo orilẹ-ède lọ.
3. Ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru; mimọ́ li on.
4. Agbara ọba fẹ idajọ pẹlu, iwọ fi idi aiṣegbe mulẹ; iwọ nṣe idajọ ati ododo ni Jakobu.
5. Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ̀: mimọ́ li on.
6. Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ̀, ati Samueli ninu awọn ti npè orukọ rẹ̀: nwọn ke pè Oluwa, o si da wọn lohùn.
7. O ba wọn sọ̀rọ ninu ọwọ̀n awọsanma: nwọn pa ẹri rẹ̀ mọ́ ati ilana ti o fi fun wọn.
8. Iwọ da wọn lohùn, Oluwa Ọlọrun wa: iwọ li Ọlọrun ti o dariji wọn, ti o si san ẹsan iṣẹ wọn.
9. Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sìn nibi òke mimọ́ rẹ̀; nitori Oluwa Ọlọrun wa mimọ́ ni.