orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 77 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú

1. EMI fi ohùn mi kigbe si Ọlọrun, ani si Ọlọrun ni mo fi ohùn mi kepè; o si fi eti si mi.

2. Li ọjọ ipọnju mi emi ṣe afẹri Ọlọrun: ọwọ mi nnà li oru, kò si rẹ̀ silẹ: ọkàn mi kọ̀ ati tù ninu.

3. Emi ranti Ọlọrun, emi kẹdun: emi ṣe aroye, ẹmi mi si rẹ̀wẹsi.

4. Iwọ kò fẹ ki emi ki o fi oju ba orun: ẹnu yọ mi tobẹ̃ ti emi kò le sọ̀rọ.

5. Emi ti nrò ọjọ atijọ, ọdun igbani.

6. Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ.

7. Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́?

8. Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai?

9. Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́?

10. Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo!

11. Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ.

12. Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ.

13. Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun?

14. Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia.

15. Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu.

16. Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ.

17. Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu.

18. Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì.

19. Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀.

20. Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.