orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 42 Yorùbá Bibeli (YCE)

IWE KEJI

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1. BI agbọnrin iti ma mi hẹlẹ si ipadò omi, Ọlọrun, bẹ̃li ọkàn mi nmi hẹlẹ si ọ.

2. Ongbẹ Ọlọrun ngbẹ ọkàn mi, ti Ọlọrun alãye: nigbawo li emi o wá, ti emi o si yọju niwaju Ọlọrun.

3. Omije mi li onjẹ mi li ọsan ati li oru, nigbati nwọn nwi fun mi nigbagbogbo pe, Ọlọrun rẹ dà?

4. Nigbati mo ba ranti nkan wọnyi, emi tú ọkàn mi jade ninu mi: emi ti ba ọ̀pọ ijọ enia lọ, emi ba wọn lọ si ile Ọlọrun, pẹlu ohùn ayọ̀ on iyìn, pẹlu ọ̀pọ enia ti npa ọjọ mimọ́ mọ́.

5. Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitori emi o sa ma yìn i sibẹ fun iranlọwọ oju rẹ̀.

6. Ọlọrun mi, ori ọkàn mi tẹ̀ ba ninu mi: nitorina li emi o ṣe ranti rẹ lati ilẹ Jordani wá, ati lati Hermoni, lati òke Misari wá.

7. Ibu omi npè ibu omi nipa hihó ṣiṣan-omi rẹ: gbogbo riru omi ati bibì omi rẹ bò mi mọlẹ.

8. Ṣugbọn Oluwa yio paṣẹ iṣeun-ifẹ rẹ̀ nigba ọ̀san, ati li oru orin rẹ̀ yio wà pẹlu mi, ati adura mi si Ọlọrun ẹmi mi.

9. Emi o wi fun Ọlọrun, apata mi pe, Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe mi? ẽṣe ti emi fi nrìn ni ìgbawẹ nitori inilara ọta nì.

10. Bi ẹnipe idà ninu egungun mi li ẹ̀gan ti awọn ọta mi ngàn mi; nigbati nwọn nwi fun mi lojojumọ pe, Ọlọrun rẹ dà?

11. Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun; nitori emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi ati Ọlọrun mi.