1. ẼṢE ti iwọ fi nṣe-fefe ninu ìwa-ìka, iwọ alagbara ọkunrin? ore Ọlọrun duro pẹ titi.
2. Ahọn rẹ ngberò ìwa-ìka; bi abẹ mimú o nṣiṣẹ ẹ̀tan.
3. Iwọ fẹ ibi jù ire lọ; ati eke jù ati sọ ododo lọ.
4. Iwọ fẹ ọ̀rọ ipanirun gbogbo, iwọ ahọn ẹ̀tan.
5. Ọlọrun yio si lù ọ bolẹ lailai, yio si dì ọ mu, yio si ja ọ kuro ni ibujoko rẹ, yio si fà ọ tu kuro lori ilẹ alãye.
6. Olododo yio ri i pẹlu, yio si bẹ̀ru, yio si ma rẹrin rẹ̀ pe,
7. Kiyesi ọkunrin ti kò fi Ọlọrun ṣe agbara rẹ̀; bikoṣe li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ li o gbẹkẹle, o si mu ara rẹ̀ le ninu ìwa buburu rẹ̀.
8. Ṣugbọn emi dabi igi olifi tutu ni ile Ọlọrun: emi gbẹkẹle ãnu Ọlọrun lai ati lailai.
9. Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ́ rẹ.