22. Ati li akokò ipọnju rẹ̀, o tun ṣe irekọja si i si Oluwa. Eyi ni Ahasi, ọba.
23. Nitori ti o rubọ si awọn oriṣa Damasku, awọn ẹniti o kọlù u: o si wipe, Nitoriti awọn oriṣa awọn ọba Siria ràn wọn lọwọ, nitorina li emi o rubọ si wọn, ki nwọn le ràn mi lọwọ. Ṣugbọn awọn na ni iparun rẹ̀ ati ti gbogbo Israeli.
24. Ahasi si kó gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun jọ, o si ké kuro lara ohun-elo ile Ọlọrun, o si tì ilẹkun ile Oluwa, o si tẹ́ pẹpẹ fun ara rẹ̀ ni gbogbo igun Jerusalemu.
25. Ati ni gbogbo orori ilu Juda li o ṣe ibi giga wọnni, lati sun turari fun awọn ọlọrun miran, o si mu Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀ binu.
26. Ati iyokù iṣe rẹ̀, ati ti gbogbo ọ̀na rẹ̀ ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.
27. Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu na, ani ni Jerusalemu; ṣugbọn nwọn kò mu u wá sinu awọn isa-okú awọn ọba Israeli: Hesekiah ọmọ rẹ si jọba ni ipò rẹ̀.