2. Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ.
3. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí.
4. Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.”
5. Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu.
6. Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí.