9. Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.
10. Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’
11. “Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,
12. Mo farabalẹ̀ fun yín,ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.
13. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’
14. Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.
15. “Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ.
16. Ṣé kí n dúró,nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì?