15. O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn,o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16. Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi,o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi.
17. O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò,o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀.
18. “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú,a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀.
19. Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta,tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ,bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo.
20. O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ,o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ.
21. Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀,a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i.
22. Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀,ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”