1. Ìran tí Amosi, ọ̀kan ninu àwọn darandaran Tekoa, rí nípa Israẹli nìyí, nígbà ayé Usaya, ọba Juda, ati Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli, ní ọdún meji ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì jìgìjìgì.
2. Amosi ní:“OLUWA bú ramúramù lórí Òkè Sioni,ó fọhùn ní Jerusalẹmu;àwọn pápá tútù rọ,ewéko tútù orí òkè Kamẹli sì rẹ̀.”
3. OLUWA ní, “Àwọn ará Damasku ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà. Wọ́n mú ohun èlò ìpakà onírin ṣómúṣómú, wọ́n fi pa àwọn ará Gileadi ní ìpa ìkà.
4. Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀.
5. N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
6. Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu.
7. N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.
8. N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.