45. Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.
46. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀.
47. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin àìmọ́ àti mímọ́ láàrin ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’ ”