Àwọn Júù pé jọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojú kọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tó kù ń bẹ̀rù u wọn.