10. “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà ḿi gbọ́tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,tàbí a ó wa rí òmìíràn lẹ́yìn mi.
11. Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12. Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kédeÈmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrin yín.Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,“Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13. Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
14. Èyí ni ohun tí Olúwa wíolùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì;“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónìláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,gbogbo ará Bábílónìnínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15. Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ.”
16. Èyí ni ohun tí Olúwa wíẸni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun,ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi,
17. ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:
18. “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19. Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.