1. “Ẹ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájúù mi ẹ̀yin erékùṣù!Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè tún agbára wọn ṣe!Jẹ́ kí wọn wá ṣíwájú kí wọn sọ̀rọ̀:Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.
2. “Ta ni ó ti ru ẹnìkan ṣókè láti ìlà-oòrùn wá,tí ó pè é ní òdodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?Ó gbé àwọn orílẹ̀ èdè lé e lọ́wọ́ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájúu rẹ̀.Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,láti kù ú níyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀.
3. Ó ń lé pa wọn ó sì tẹ̀ṣíwájú láì farapa,ní ojú ọ̀nà tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí.
4. Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹnì kìn-ín-ní wọnàti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi ni ẹni náà.”
5. Àwọn erékùsù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.Wọ́n súnmọ́tòsí wọ́n sì wá síwájú
6. Èkínní ran èkejì lọ́wọ́ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé“Jẹ́ alágbára!”
7. Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú,àti ẹni tí ó fi òòlù dán anmú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú.Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.”Ó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀.
8. “Ṣùgbọ́n ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ mi,Jákọ́bù, ẹni tí mo ti yàn,ẹ̀yin ìran Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ mi,
9. mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;’Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
10. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ;má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.
11. “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹni yẹ̀yẹ́;gbogbo àwọn tí ó lòdì sí ọyóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.
12. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀ta rẹ,ìwọ kì yóò rí wọn.Gbogbo àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóò dàbí òfuuru gbádá.
13. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mútí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.