18. Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?
19. Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ótí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.
20. Ọkùnrin kan tí ó talákà ju kí ó lè múirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,wá igi tí kò le è rà.Ó wá oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.
21. Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ìwọ kò tí ì gbọ́?A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpilẹ̀ ayé?
22. Òun jókòó lórí Ìtẹ́ ní òkè òbììrí ilẹ̀ ayé,àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
23. Ó sọ àwọn ọmọ ọba di aṣánàti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.
24. Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,kété tí a gbìn wọ́n,kété tí wọ́n tita ẹ̀kan nínú ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,bẹ́ ni ìji-líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.
25. “Ta ni ẹ ó fi mi wé?Tàbí ta ni ó bámi dọ́gba?” ni Ẹni-Mímọ́ wí.
26. Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wo àwọn ọ̀run:Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kantí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,ọ̀kanṣoṣo nínú wọn kò sọnù.