47. Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ ọ wa.”
48. Bí Fílístínì ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dáfídì yára sáré sí oun náà láti pàdé e rẹ̀.
49. Ó ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀ ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Fílístínì. Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀.
50. Dáfídì yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Fílístínì pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, láìsí idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó lu Fílístínì ó sì pa á.