Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 8:17-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa.

18. Nigbati Jesu ri ọ̀pọlọpọ enia lọdọ rẹ̀, o paṣẹ fun wọn lati lọ si apa keji adagun.

19. Akọwe kan si tọ̀ ọ wá, o wi fun u pe, Olukọni, emi ó mã tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ nlọ.

20. Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le.

21. Ekeji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinkú baba mi na.

22. Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Iwọ mã tọ̀ mi lẹhin, si jẹ ki awọn okú ki o mã sin okú ara wọn.

23. Nigbati o si bọ si ọkọ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tẹ̀le e.

24. Si wò o, afẹfẹ nla dide ninu okun tobẹ̃ ti riru omi fi bò ọkọ̀ mọlẹ; ṣugbọn on sùn.

25. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn ji i, nwọn wipe, Oluwa, gbà wa, awa gbé.

26. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe ojo bẹ̃, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Nigbana li o dide, o si ba afẹfẹ ati okun wi; idakẹrọrọ si de.

27. Ṣugbọn ẹnu yà awọn ọkunrin na, nwọn wipe, Irú enia wo li eyi, ti afẹfẹ ati omi okun gbọ tirẹ̀?

Ka pipe ipin Mat 8