Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 6:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ kiyesi ara ki ẹ máṣe itọrẹ anu nyin niwaju enia, ki a ba le ri nyin: bi o ba ri bẹ̃, ẹnyin ko li ère lọdọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun.

2. Nitorina nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe fun fère niwaju rẹ, bi awọn agabagebe ti nṣe ni sinagogu ati ni ita, ki nwọn ki o le gbà iyìn enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.

3. Ṣugbọn nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ́ òsi rẹ ki o mọ̀ ohun ti ọwọ́ ọtún rẹ nṣe;

4. Ki itọrẹ ãnu rẹ ki o le wà ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ, on tikararẹ̀ yio san a fun ọ ni gbangba.

5. Nigbati iwọ ba ngbadura, máṣe dabi awọn agabagebe; nitori nwọn fẹ ati mã duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọ̀na ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.

6. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.

7. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn.

8. Nitorina ki ẹnyin máṣe dabi wọn: Baba nyin sá mọ̀ ohun ti ẹnyin ṣe alaini, ki ẹ to bère lọwọ rẹ̀.

9. Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.

10. Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye.

11. Fun wa li onjẹ õjọ wa loni.

12. Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa.

Ka pipe ipin Mat 6