Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 26:35-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Peteru wi fun u pe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi kò jẹ sẹ́ ọ. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin wi pẹlu.

36. Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi.

37. O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì.

38. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na.

39. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.

40. O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan?

41. Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara.

42. O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu u, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.

43. O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun.

44. O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna.

45. Nigbana li o tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: wo o, wakati kù fẹfẹ, ti a o si fi Ọmọ-ẹnia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ.

46. Ẹ dide, ki a mã lọ: wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.

47. Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá.

48. Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu ko li ẹnu, on na ni: ẹ mú u.

49. Lojukanna o wá sọdọ Jesu, o si wipe, Alafia, Olukọni; o si fi ẹnu ko o li ẹnu.

50. Jesu si wi fun u pe, Ọrẹ́, nitori kini iwọ fi wá? Nigbana ni nwọn wá, nwọn si gbé ọwọ́ le Jesu, nwọn si mu u.

Ka pipe ipin Mat 26