Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 24:19-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni!

20. Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi:

21. Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si.

22. Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru.

23. Nigbana bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, Wo o, Kristi mbẹ nihin, tabi lọhun; ẹ máṣe gbà a gbọ́.

24. Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolĩ yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu nla hàn; tobẹ̃ bi o le ṣe ṣe nwọn o tàn awọn ayanfẹ pãpã.

25. Wo o, mo wi fun nyin tẹlẹ.

26. Nitorina bi nwọn ba wi fun nyin pe, Wo o, o wà li aginjù; ẹ má lọ sibẹ̀: wo o, o wà ni iyẹwu; ẹ máṣe gbàgbọ́.

27. Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de ìwọ-õrun; bẹ̃ni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu.

28. Nitori ibikibi ti oku ba gbé wà, ibẹ̀ li awọn igúnnugún ikojọ pọ̀ si.

29. Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mì titi:

30. Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.

31. Yio si rán awọn angẹli rẹ̀ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji.

32. Njẹ ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile:

33. Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun.

34. Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

Ka pipe ipin Mat 24