Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 14:13-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nigbati Jesu si gbọ́, o dide kuro nibẹ̀, o ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù, on nikan; nigbati awọn enia si gbọ́, nwọn si ti ilu wọn rìn tọ̀ ọ li ẹsẹ.

14. Jesu jade lọ, o ri ọ̀pọlọpọ enia, inu rẹ̀ si yọ́ si wọn, o si ṣe dida arùn ara wọn.

15. Nigbati o di aṣalẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si kọja tan: rán ijọ enia lọ, ki nwọn ki o le lọ si iletò lọ irà onjẹ fun ara wọn.

16. Jesu si wi fun wọn pe, Nwọn kò ni ilọ; ẹ fun wọn li onjẹ.

17. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun ati ẹja meji nihinyi.

18. O si wipe, Ẹ mu wọn fun mi wá nihinyi.

19. O si paṣẹ ki ijọ enia joko lori koriko, o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na; nigbati o gbé oju soke ọrun, o sure, o si bù u, o fi akara na fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia.

20. Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó; nwọn si ko ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n mejila kún.

21. Awọn ti o si jẹ ẹ to ìwọn ẹgbẹ̃dọgbọn ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde.

22. Lojukanna Jesu si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o ṣiwaju rẹ̀ lọ si apakeji, nigbati on tú ijọ enia ká.

23. Nigbati o si tú ijọ enia ká tan, o gùn ori òke lọ, on nikan, lati gbadura: nigbati alẹ si lẹ, on nikan wà nibẹ̀.

24. Ṣugbọn nigbana li ọkọ̀ wà larin adagun, ti irumi ntì i siwa sẹhin: nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn.

25. Nigbati o di iṣọ kẹrin oru, Jesu tọ̀ wọn lọ, o nrìn lori okun.

26. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i ti o nrìn lori okun, ẹ̀ru bà wọn, nwọn wipe, Iwin ni; nwọn fi ibẹru kigbe soke.

Ka pipe ipin Mat 14