Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 12:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ.

2. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi.

3. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀:

4. Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa?

5. Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi?

6. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin.

7. Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi.

8. Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi.

9. Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn.

10. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀.

11. O si wi fun wọn pe, ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke?

Ka pipe ipin Mat 12