orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 1 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìran Jesu Kristi

1. IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu.

2. Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀;

3. Juda si bí Faresi ati Sara ti Tamari; Faresi si bí Esromu; Esromu si bí Aramu;

4. Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni;

5. Salmoni si bí Boasi ti Rakabu; Boasi si bí Obedi ti Rutu; Obedi si bí Jesse;

6. Jesse si bí Dafidi ọba. Dafidi ọba si bí Solomoni lati ọdọ ẹniti o ti nṣe aya Uria;

7. Solomoni si bí Rehoboamu; Rehoboamu si bí Abia; Abia si bí Asa;

8. Asa si bí Jehosafati; Jehosafati si bí Joramu; Joramu si bí Osia;

9. Osia si bí Joatamu; Joatamu si bí Akasi; Akasi si bí Hesekiah;

10. Hesekiah si bí Manasse; Manasse si bí Amoni; Amoni si bí Josiah;

11. Josiah si bí Jekoniah ati awọn arakunrin rẹ̀, nigba ikolọ si Babiloni.

12. Lẹhin ikolọ si Babiloni ni Jekoniah bí Sealtieli; Sealtieli si bí Serubabeli;

13. Serubabeli si bí Abiudu; Abiudu si bí Eliakimu; Eliakimu si bí Asoru;

14. Asoru si bí Sadoku; Sadoku si bí Akimu; Akimu si bí Eliudu;

15. Eliudu si bí Eleasa; Eleasa si bí Matani; Matani si bí Jakọbu;

16. Jakọbu si bí Josefu ọkọ Maria, lati ọdọ ẹniti a bí Jesu, ti a npè ni Kristi.

17. Bẹ̃ni gbogbo iran lati Abrahamu wá de Dafidi jẹ iran mẹrinla; ati lati Dafidi wá de ikolọ si Babiloni jẹ iran mẹrinla; ati lati igba ikólọ si Babiloni de igba Kristi o jẹ iran mẹrinla.

Ìtàn Ìbí Jesu Kristi

18. Bi ibí Jesu Kristi ti ri niyi: li akokò ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josefu, ki nwọn to pade, a ri i, o lóyun lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.

19. Josefu ọkọ rẹ̀, ti iṣe olõtọ enia, ko si fẹ dojutì i ni gbangba, o fẹ ikọ̀ ọ silẹ ni ìkọkọ.

20. Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angẹli Oluwa yọ si i li oju alá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má fòiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ ni.

21. Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn.

22. Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe,

23. Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa.

24. Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ̀, o ṣe bi angẹli Oluwa ti wi fun u, o si mu aya rẹ̀ si ọdọ:

25. On ko si mọ̀ ọ titi o fi bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin: o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.