Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 6:40-55 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Nwọn si joko li ẹgbẹgbẹ li ọrọrun ati li aradọta.

41. Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn.

42. Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó.

43. Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu.

44. Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.

45. Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká.

46. Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura.

47. Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ.

48. O si ri nwọn nṣiṣẹ ni wiwà ọkọ̀; nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn: nigbati o si di ìwọn iṣọ kẹrin oru, o tọ̀ wọn wá, o nrìn lori okun, on si nfẹ ré wọn kọja.

49. Ṣugbọn nigbati nwọn ri ti o nrìn loju omi, nwọn ṣebi iwin ni, nwọn si kigbe soke:

50. Nitori gbogbo wọn li o ri i, ti ẹ̀ru si ba wọn. Ṣugbọn lojukanna o si ba wọn sọ̀rọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ tújuka: Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.

51. O si wọ̀ inu ọkọ̀ tọ̀ wọn lọ; afẹfẹ si da: ẹ̀ru si ba wọn rekọja gidigidi ninu ara wọn, ẹnu si yà wọn.

52. Nwọn kò sá ronu iṣẹ iyanu ti iṣu akara: nitoriti ọkàn wọn le.

53. Nigbati nwọn si rekọja tan, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti, nwọn si sunmọ eti ilẹ.

54. Bi nwọn si ti njade lati inu ọkọ̀ wá, lojukanna nwọn si mọ̀ ọ,

55. Nwọn si sare lọ si gbogbo igberiko yiká, nwọn bẹ̀rẹ si ima gbé awọn ti ara wọn ṣe alaida wá lori akete, si ibiti nwọn gbọ́ pe o wà.

Ka pipe ipin Mak 6