Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 6:2-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

3. Gbẹnagbẹna na kọ yi, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Jose, ati ti Juda, ati Simoni? awọn arabinrin rẹ̀ kò ha si wà nihinyi lọdọ wa? Nwọn si kọsẹ̀ lara rẹ̀.

4. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀.

5. On ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ̀, jù pe o gbé ọwọ́ rẹ̀ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada.

6. Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni.

7. O si pè awọn mejila na sọdọ rẹ̀, o bẹ̀rẹ si irán wọn lọ ni meji-meji; o si fi aṣẹ fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́;

8. O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe mu ohunkohun, lọ si àjo wọn, bikoṣe ọpá nikan; ki nwọn ki o máṣe mu àpo, tabi akara, tabi owo ninu asuwọn wọn:

9. Ṣugbọn ki nwọn ki o wọ̀ salubàta: ki nwọn máṣe wọ̀ ẹ̀wu meji.

Ka pipe ipin Mak 6