Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 2:22-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ko si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bi bẹ̃kọ ọti-waini titun a bẹ́ ìgo na, ọti-waini a si danu, ìgo na a si fàya; ṣugbọn ọti-waini titun ni ã fi sinu ìgo titun.

23. O si ṣe, bi Jesu ti nkọja lọ lãrin oko ọkà li ọjọ isimi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà bi nwọn ti nlọ.

24. Awọn Farisi si wi fun u pe, Wo o, ẽṣe ti nwọn fi nṣe eyi ti kò yẹ li ọjọ isimi?

25. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati o ṣe alaini, ti ebi si npa a, on, ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀?

26. Bi o ti wọ̀ inu ile Ọlọrun lọ li ọjọ Abiatari olori alufa, ti o si jẹ akara ifihàn, ti ko tọ́ fun u lati jẹ bikoṣe fun awọn alufa, o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu?

27. O si wi fun wọn pe, A dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi:

28. Nitorina Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi pẹlu.

Ka pipe ipin Mak 2