Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 16:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI ọjọ isimi si kọja, Maria Magdalene, ati Maria iya Jakọbu, ati Salome rà turari ki nwọn ba wá lati fi kùn u.

2. Ni kutukutu owurọ̀ ọjọ kini ọ̀sẹ, nwọn wá si ibi iboji nigbati õrùn bẹ̀rẹ si ilà.

3. Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Tani yio yi okuta kuro li ẹnu ibojì na fun wa?

4. Nigbati nwọn si wò o, nwọn ri pe a ti yi okuta na kuro: nitoripe o tobi gidigidi.

5. Nigbati nwọn si wọ̀ inu ibojì na, nwọn ri ọmọkunrin kan joko li apa ọtún, ti o wọ̀ agbada funfun; ẹ̀ru si ba wọn.

6. O si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin nwá Jesu ti Nasareti, ti a kàn mọ agbelebu: o jinde; kò si nihinyi: ẹ wò ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.

Ka pipe ipin Mak 16