Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 13:24-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn;

25. Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi.

26. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo.

27. Nigbana ni yio si rán awọn angẹli rẹ̀, yio si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun aiye titi de ikangun ọrun.

28. Nisisiyi ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; Nigbati ẹ̀ka rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile:

29. Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun.

30. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi kì yio rekọja, titi a o fi mu gbogbo nkan wọnyi ṣẹ.

31. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

32. Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.

33. Ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã gbadura: nitori ẹnyin ko mọ̀ igbati akokò na yio de.

34. Nitori Ọmọ-enia dabi ọkunrin kan ti o lọ si àjo ti o jìna rére, ẹniti o fi ile rẹ̀ silẹ, ti o si fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iṣẹ olukuluku fun u, ti o si fi aṣẹ fun oluṣọna ki o mã ṣọna.

35. Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin ko mọ̀ igba ti bãle ile mbọ̀wá, bi li alẹ ni, tabi larin ọganjọ, tabi li akukọ, tabi li owurọ̀:

36. Pe, nigbati o ba de li ojijì, ki o máṣe ba nyin li oju orun.

37. Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mã ṣọna.

Ka pipe ipin Mak 13