Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 13:1-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BI o si ti nti tẹmpili jade, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wipe, Olukọni, wò irú okuta ati irú ile ti o wà nihinyi!

2. Jesu si dahùn wi fun u pe, Iwọ ri ile nla wọnyi? kì yio si okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.

3. Bi o si ti joko lori òke Olifi ti o kọju si tẹmpili, Peteru ati Jakọbu, ati Johanu ati Anderu, bi i lẽre nikọ̀kọ wipe,

4. Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi nigbati gbogbo nkan wọnyi yio ṣẹ?

5. Jesu si da wọn lohùn, o bẹ̀rẹ si isọ fun wọn pẹ, Ẹ mã kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ:

6. Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ.

7. Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi.

8. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju.

9. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn.

10. A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède.

11. Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́.

12. Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn.

13. Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.

14. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke:

15. Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o máṣe sọkalẹ lọ sinu ile, bẹ̃ni ki o má si ṣe wọ̀ inu rẹ̀, lati mu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀:

16. Ati ki ẹniti mbẹ li oko ki o maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀.

17. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmu fun ọmọ mu li ọjọ wọnni!

18. Ki ẹ si ma gbadura, ki sisá nyin ki o máṣe bọ́ si igba otutù.

19. Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si.

Ka pipe ipin Mak 13