Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 10:46-52 Yorùbá Bibeli (YCE)

46. Nwọn si wá si Jeriko: bi o si ti njade kuro ni Jeriko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ awọn enia, Bartimeu afọju, ọmọ Timeu, joko lẹba ọ̀na, o nṣagbe.

47. Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Nasareti ni, o bẹ̀rẹ si ikigbe lohùn rara, wipe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.

48. Ọpọlọpọ si ba a wipe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i jù bẹ̃ lọ pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.

49. Jesu si dẹsẹ duro, o si paṣẹ pe ki a pè e wá. Nwọn si pè afọju na, nwọn wi fun u pe, Tùjuka, dide; o npè ọ.

50. O si bọ ẹ̀wu rẹ́ sọnù, o dide, o si tọ̀ Jesu wá.

51. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe fun ọ? Afọju na si wi fun u pe, Rabboni, ki emi ki o le riran.

52. Jesu si wi fun u pe, Mã lọ; igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. Lojukanna, o si riran, o si tọ̀ Jesu lẹhin li ọ̀na.

Ka pipe ipin Mak 10