Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 9:16-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn.

17. Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe.

18. Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju.

19. Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi?

20. Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju:

21. Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀.

22. Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu.

23. Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre.

24. Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe.

25. Nitorina o dahùn o si wipe, Bi ẹlẹṣẹ ni, emi kò mọ̀: ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi.

26. Nitorina nwọn wi fun u pe, Kili o ṣe si ọ? o ti ṣe là ọ loju?

27. O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi?

28. Nwọn si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si wipe, Iwọ li ọmọ-ẹhin rẹ̀; ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose li awa.

29. Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá.

Ka pipe ipin Joh 9