Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 6:39-57 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.

40. Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.

41. Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá.

42. Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? etiṣe wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá?

43. Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin.

44. Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.

45. A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá.

46. Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba.

47. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun.

48. Emi li onjẹ ìye.

49. Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú.

50. Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú.

51. Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.

52. Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ?

53. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin.

54. Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.

55. Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ.

56. Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀.

57. Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.

Ka pipe ipin Joh 6