Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 6:25-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi?

26. Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó.

27. Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí.

28. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun?

29. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́.

30. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? iṣẹ kini iwọ ṣe?

31. Awọn baba wa jẹ manna li aginjù; gẹgẹ bi a ti kọ o pe, O fi onjẹ fun wọn jẹ lati ọrun wá.

32. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá.

33. Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye.

34. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai.

35. Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.

36. Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́.

37. Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.

38. Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.

39. Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.

40. Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.

41. Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá.

42. Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? etiṣe wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá?

43. Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin.

Ka pipe ipin Joh 6