Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 4:36-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀.

37. Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ.

38. Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ.

39. Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi.

40. Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji.

41. Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀;

42. Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.

43. Lẹhin ijọ meji o si ti ibẹ̀ kuro, o lọ si Galili.

44. Nitori Jesu tikararẹ̀ ti jẹri wipe, Woli ki ini ọlá ni ilẹ on tikararẹ̀.

45. Nitorina nigbati o de Galili, awọn ara Galili gbà a, nitoriti nwọn ti ri ohun gbogbo ti o ṣe ni Jerusalemu nigba ajọ; nitori awọn tikarawọn lọ si ajọ pẹlu.

46. Bẹ̃ni Jesu tún wà si Kana ti Galili, nibiti o gbé sọ omi di waini. ọkunrin ọlọla kan si wà, ẹniti ara ọmọ rẹ̀ kò da ni Kapernaumu.

47. Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú.

48. Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Bikoṣepe ẹnyin ba ri àmi ati iṣẹ iyanu, ẹnyin kì yio gbagbọ́ lai.

49. Ọkunrin ọlọla na wi fun u pe, Oluwa, sọkalẹ wá, ki ọmọ mi ki o to ku.

50. Jesu wi fun u pe, Mã ba ọ̀na rẹ lọ; ọmọ rẹ yè. ọkunrin na si gbà ọ̀rọ ti Jesu sọ fun u gbọ́, o si lọ.

Ka pipe ipin Joh 4