Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 4:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ.

11. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na?

12. Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀?

13. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ:

14. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.

15. Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin.

16. Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi.

17. Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ:

Ka pipe ipin Joh 4