Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 2:6-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta.

7. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti.

8. O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ.

9. Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo,

10. O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi.

11. Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.

12. Lẹhin eyi, o sọkalẹ lọ si Kapernamu, on ati iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nwọn kò si gbé ibẹ̀ li ọjọ pupọ.

13. Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu,

14. O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko:

15. O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu.

16. O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità.

17. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ranti pe, a ti kọ ọ pe, Itara ile rẹ jẹ mi run.

18. Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi?

Ka pipe ipin Joh 2