Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 17:19-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ.

20. Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn;

21. Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi.

22. Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan;

23. Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pé li ọ̀kan; ki aiye ki o le mọ̀ pe, iwọ li o rán mi, ati pe iwọ si fẹràn wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹràn mi.

24. Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mã wò ogo mi, ti iwọ ti fi fifun mi: nitori iwọ sá fẹràn mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aiye.

25. Baba olododo, aiye kò mọ̀ ọ: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, awọn wọnyi si mọ̀ pe iwọ li o rán mi.

26. Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, emi ó si sọ ọ di mimọ̀: ki ifẹ ti iwọ fẹràn mi, le mã wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.

Ka pipe ipin Joh 17