Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 11:54-57 Yorùbá Bibeli (YCE)

54. Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

55. Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́.

56. Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ?

57. Njẹ awọn olori alufa ati awọn Farisi ti paṣẹ pe bi ẹnikan ba mọ̀ ibi ti o gbé wà, ki o fi i hàn, ki nwọn ki o le mu u.

Ka pipe ipin Joh 11