Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jak 5:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ẹ máṣe kùn si ọmọnikeji nyin, ará, ki a má bã dá nyin lẹbi: kiyesi i, onidajọ duro li ẹnu ilẹkun.

10. Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru.

11. Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu.

12. Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.

13. Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́.

14. Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa:

15. Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i.

16. Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.

17. Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa.

18. O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade.

19. Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada;

Ka pipe ipin Jak 5