Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Pet 2:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn.

2. Ọpọlọpọ ni yio si mã tẹle ìwa wọbia wọn; nipa awọn ẹniti a o fi mã sọ ọrọ-odi si ọ̀na otitọ.

3. Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé.

4. Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ;

5. Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun;

6. Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun;

7. O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ:

8. (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́):

9. Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ:

Ka pipe ipin 2. Pet 2