orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 9 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọrẹ fún Àwọn Onigbagbọ

1. NITORI nipa ti ipinfunni fun awọn enia mimọ́, kò ni pe mo nkọwe si nyin ju bẹ̃ lọ.

2. Nitori mo mọ̀ imura-tẹlẹ nyin, eyiti mo fi yangàn fun awọn ara Makedonia nitori nyin, pe, Akaia ti mura tan niwọn ọdún kan ti o kọja; itara nyin si ti rú ọ̀pọlọpọ soke.

3. Ṣugbọn mo ti rán awọn arakunrin, ki iṣogo wa nitori nyin ki o máṣe jasi asan niti ọ̀ran yi; pe gẹgẹ bi mo ti wi, ki ẹnyin ki o le mura tẹlẹ:

4. Bi awọn ninu ará Makedonia ba bá mi wá, ti nwọn si bá nyin li aimura tẹlẹ, ki oju ki o máṣe tì wa (laiwipe ẹnyin,) niti igbẹkẹle yi.

5. Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro.

6. Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká.

7. Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ.

8. Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo:

9. (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai.

10. Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.)

11. Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa.

12. Nitori iṣẹ-iranṣẹ ìsin yi kò fi kun iwọn aini awọn enia mimọ́ nikan, ṣugbọn o tubọ pọ si i nipa ọ̀pọlọpọ ọpẹ́ si Ọlọrun,

13. Lẹhin ti nwọn fi iṣẹ-isin yi dan nyin wo, nwọn yin Ọlọrun li ogo fun itẹriba ijẹwọ́ nyin si ihinrere Kristi, ati fun ilàwọ ìdawó nyin fun wọn ati fun gbogbo enia;

14. Nigbati awọn tikarawọn pẹlu ẹ̀bẹ nitori nyin nṣafẹri nyin nitori ọpọ ore-ọfẹ Ọlọrun ti mbẹ ninu nyin.

15. Ọpẹ́ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ ẹ̀bun rẹ̀.