Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 2:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ wahalà ati arodun ọkan mi ni mo ti fi ọ̀pọlọpọ omije kọwe si nyin; kì iṣe nitori ki a le bà nyin ninu jẹ, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ ifẹ ti mo ni si nyin lọpọlọpọ rekọja.

5. Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba ti mu ibinujẹ wá, on kò bà mi ni inu jẹ, bikoṣe niwọn diẹ: ki emi ki o máṣe di ẹru l'ẹ̀ru gbogbo nyin.

6. Ìya yi ti ọpọlọpọ ti fi jẹ iru enia bẹ̃, o to fun u.

7. Kaka bẹ ẹ, ẹnyin iba kuku darijì i, ki ẹ si tù u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má bã bò iru enia bẹ̃ mọlẹ.

8. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ fi ifẹ nyin han daju si oluwarẹ̀.

9. Nitori eyi na pẹlu ni mo ti kọwe, ki emi ki o le mọ̀ ẹri nyin, bi ẹnyin ba ṣe eletí ọmọ li ohun gbogbo.

10. Ṣugbọn ẹniti ẹnyin ba fi ohunkohun jì fun, emi fi jì pẹlu: nitori ohun ti emi pẹlu ba ti fi jì, bi mo ba ti fi ohunkohun jì, nitori tinyin ni mo ti fi ji niwaju Kristi.

11. Ki Satani má bã rẹ́ wa jẹ: nitori awa kò ṣe alaimọ̀ arekereke rẹ̀.

12. Ṣugbọn nigbati mo de Troa lati wãsu ihinrere Kristi, ti ilẹkun si ṣí silẹ fun mi lati ọdọ Oluwa wá,

Ka pipe ipin 2. Kor 2