Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 12:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI ko le ṣe aiṣogo bi kò tilẹ ṣe anfani. Nitori emi ó wá si iran ati iṣipaya Oluwa.

2. Emi mọ̀ ọkunrin kan ninu Kristi ni ọdún mẹrinla sẹhin, (yala ninu ara ni, emi kò mọ̀; tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀; Ọlọrun ni o mọ): a gbé irú enia bẹ̃ lọ si ọ̀run kẹta.

3. Emi si ti mọ̀ irú ọkunrin bẹ̃, (yala li ara ni, tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀: Ọlọrun mọ̀)

4. Bi a ti gbé e lọ soke si Paradise, ti o si gbọ́ ọ̀rọ ti a kò le sọ, ti kò tọ́ fun enia lati mã sọ.

5. Nipa irú ẹni bẹ̃ li emi ó ma ṣogo: ṣugbọn nipa ti emi tikarami emi kì yio ṣogo, bikoṣe ninu ailera mi.

6. Nitoripe bi emi tilẹ nfẹ mã ṣogo, emi kì yio jẹ aṣiwère; nitoripe emi ó sọ otitọ: ṣugbọn mo kọ̀, ki ẹnikẹni ki o má bã fi mi pè jù ohun ti o ri ti emi jẹ lọ, tabi ju eyiti o gbọ lẹnu mi.

7. Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja.

8. Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi.

Ka pipe ipin 2. Kor 12