Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 1:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PAULU Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, si ijọ Ọlọrun ti o wà ni Korinti, pẹlu, gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà ni gbogbo Akaia:

2. Õre-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

3. Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo;

4. Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.

5. Nitoripe bi ìya Kristi ti di pipọ ninu wa, gẹgẹ bẹ̃ni itunu wa di pipọ pẹlu nipa Kristi.

Ka pipe ipin 2. Kor 1